Yoruba Ancestor
History of Yorubas
Yoruba People and Culture
ORIKI ILE YORUBA
IBADAN
Ibadan mesi Ogo, nile Oluyole. Ilu Ogunmola, olodogbo keri loju
ogun. Ilu Ibikunle alagbala jaya-jaya. Ilu Ajayi, o gbori Efon se filafila.
Ilu Latosa, Aare-ona kakanfo. Ibadan Omo ajoro sun. Omo a je Igbin yoo,
fi ikarahun fo ri mu. Ibadan maja-maja bii tojo kin-in-ni, eyi too ja aladuugbo
gbogbo logun, Ibadan ki ba ni s’ore ai mu ni lo s’ogun. Ibadan Kure! Ibadan
beere ki o too wo o, Ni bi Olè gbe n jare Olohun. B’Ibadan ti n gbonile bee lo
n gba Ajoji. Eleyele lomi ti teru-tomo ‘Layipo n mu. Asejire lomi abumu-
buwe nile Ibadan. A ki waye ka maa larun kan lara, Ija igboro larun Ibadan.
IJEBU
Ijebu omo alare, omo awujale, omo arojo joye, omo alagemo
ogun woyowoyo, Omo aladiye ogogomoga, omo adiye balokun
omilili, ara orokun, ara o radiye, omo ohun seni oyoyonyo,
oyoyo mayomo ohun seni olepani, omo dudu ile komobe se
njosi, pupa tomo be se okuku sinle, omo moreye mamaroko,
morokotan eye matilo, omo moni isunle mamalobe, obe tin
benile komoile baba tobiwan lomo,
Omo onigbo ma’de, omo onigbo mawo mawo, omo onigbo
ajoji magbodowo, ajoji tobawo gboro yio di ebora ile baba tobi
wan lomo. Ijebu omo ere niwa, omo olowo isembaye, towo kuji
to dode, koto dowo eru, koto dowo omo. Orisa jendabi onile yi,
niwan finpe igba ijebu owo, kelebe ijebu owo, ito ijebu owo,
dudu ijebu owo, pupa ijebu owo, kekere ijebu owo, agba ijebu
owo. Ijebu ode ijebu ni, ijebu igbo ijebu ni, ijebu isara ijebu ni,
ayepe ijebu, ikorodu ijebu ijebu noni, Ijebu Omo Oni Ile nla,
Ijebu Omo Alaso nla! Ajuwaase ooo
EGBA
Egba mo’lisa omo gbongbo akala
Omo erin jogun ola.
Omo osi’lekun pa’lekun de
Aridi ogo loju Ogun.
Omo eni dudu osi nile, pupa towa nle o mo’bese
Egba ara ake majo.
Omo majojo lofa, jojo lofa kunkun din jeni
Omo ajo gberu majo gbeko
Eru ni nsini eko ki nsi nyan
Egba omo oru la nse’ka
Eyan to seru e losan lojo si nko? Oni toun koni le farare lo
Omo ateni wijo wiijo wijo ti run e ama gbon le terere
Egba meji ko le j’ara won liyan, bikan banwi, ekeji ama wipe bawa
Edumare Jowo Bawa Da Ilu Egba Si. Ase
IJESHA
In pele o gbogbo eyin Ijesha,
Ijesha omo owa, omo ekun, omo bokun remi,
Ijesha tio je obi oju loro, omo du apona da,
Ijesha omo eleni ate iika,
Omo eleni ewele.
Omo olobi kan wowotiriwo,
omo olobikan wowotiriwo,
Eyi tofe teni awo seru eni, eyi tio fe teni awo sinu igbo,
Omo Ogedengbe, agbogun gboro, adi pon pon l’oju ogun,
Edumare bawa da ilu Ijesha si o
Ase
OSOGBO
Osogbo oroki asala omo onile obi osogbo ilu aro,omo aro dede bi okun aare
o peta arepeta mogba o,osun osogbo pele o,epele o eyin olomoyoyo osgbo
oroki gbe onile,otun gbe ajoji osogbo oroki,osogbo oroki omo yeye osun yeye
atewogbeja,aniyun labebe oroki ti eja nla soro, ti ran iko nise osun osogbo, rere
ni osun fun mi oroki onile obi,alaro omo asala
Edumare Jowo Bawa Da Ilu OSOSGBO si
Ase
EFON ALAYE
1. Efon npele omo oloke
Oke – ko ma ‘Laye tile ogun
Edu Ule Ahun Efon kumoye
Lomode lagba lule loko
Ibi an bini na se
In mo mo gbagbe Ule
Efon – Eye o la ke le Efon
Olorun laba ri a.
Efon npele omo oloke,
Edu Ule Ahun Efon kumoye
2. Oba Laye l’Efon,
Uwarafa mefa kete,
Indi Efon mu gbonin – gbonin
Akanda Ulu Olodumare
Afefe ibeo tuni lara
Omi ibe a mu fokan bale ni
Un kejarun, o jina s’Efon.
Efon npele omo oloke
Edu Ule Ahun Efon kumoye.
3. Iyo l’Efon re lau jo ero
Un da an da an mani
Aaye, Obalu, Ejigan, Emo,
Usaja, Ukagbe, Usokan
Efon in dimu gbonin-gbonin
Efon npele omo oloke
Edu Ule Ahun Efon kumoye
TAPA
Ọmọ Olubisi
Ọmọ aláro tin jogun ẹsin
Ọsọ eyi yẹ Tápà abiru ti ẹmi
Ọmọ ajifowurọ dana kulikuli
Ẹsọ wẹrẹ ara Ilodo nle Olubisi
Àyè Tapa lo wun mi
Boba digba oku Tapa mi o ni si nle
Wọn ni ẹ wo’tutu owu
Wọn ni ẹ wa’fara oyin
Otutu owu sọpọ
Afara oyin sọwọn gogo
Ọmọ adada-ku-ada
Ọmọ Onilero ti f’ẹsẹ jo bi iji
Ọmọ elegun mọ na n mọ
Adẹẹgbẹẹ mo se’bo ti na mi lekan ni?
Ọmọ onigunu ari nawo
Ọmọ onigunu ariyọ sẹsẹ
Ọmọ onigun ti fi kulikuli sọdun
Ẹ wi fẹni ti o gbọ
Ẹ ro fẹni ti o mọ
Ẹ sọ fun wọn pe Tapa loni’gunu
Ọsẹ wẹwẹ ara Ilodo
Olubisi ọmọ alaro lo lẹsin.
.
ILE IFE
Ife ooye lagbo. Omo olodo kan oteere. Omo olodo kan otaara.
Odo to san wereke, to san wereke, to dehinkunle oshinle to dabata
To dehinkunle adelawe to dokun
Onikee ko gbodo bu mu. Ababaja won ko gbodo Buwe
Ogedegede onisoboro ni yio mu omi do naa gbe
Soboro mi wumi, eje ki ibi dandan maa ba alabe
Won kii duro ki wa nife ooni, won kii bere ki wa nife ooye
Ko ga, ko bere laa ki wa nife oodaye
Bi won ko si ki wa nife, won kii to abere
Oju bintin la fi n wo ni. Emi wa ki oba nife, mo lo akun
Oba nii lo sese efun. Adimula,won a ni apalado
Bante gbooro,ni mufe wumi. Segi owo ati tese,
Kafari apakan ka dapakan si. Yeepa orisa, aso funfun
Oun nii mu ile olufe wumi. Apadari eni, apalado eniyan
Ebo ojoojumo, nii mu ile won su nii lo. Awa lomo oni fitila rebete
Ina ko nii ku nibe tosan toru. Ibe ni baba wa gbe n ka owo eyo
Awa lomo onilu kan, ilu kan. Ti won n fawo ekun se
Aketepe eti erin ni won fi nse osan re. Onikeke ko gbodo jo
Ababaja ko gbodo yese. Kikida onisoboro ni yio jo ilu naa ya
Ogun ko see da gbe. Baba taani ko mo wipe irin ti po lagbede
Oun ti o ba mu alagbede,ko ni mu eni to n fin ina
OYO
A ji se bi Oyolaa ri, Oyo O je se bi baba eni kankan
Oyo mo l’ afin Ojo pa Sekere, omo Atiba
Babalawo lo d’ fa, pe ibiti ilẹ gbe yọ ni aye won
Oyo ode oni,ni Ago-Ajo, Oba lo tun te, laye Atiba
A ki ro’ ba fin la le de Oyo, O ya e je a lo ree ki Alaafin
Omo a jowu yo ko lenu, A bi Ila toto lehin
Pan-du-ku bi soo ro, Ibi ti won ti ni ki Olowo gbowo
Ki Iwofa so to wo re nu, Se ko le ba di’ ja, ko le ba di apon
Ki Oba Alade le ri n je Oba, Oba taa ri, taa ka po la po, taa ko fa, lo fa,
Taa ka pata,lo ri Apata, Bembe n ro, imule lehin agbara,
Odofin ijaye,o je du ro de la kanlu, omo a ja ni le ran gangan,
Eji ogboro, Alaafin Atiba, Oba lo ko wo je, Ko to do ri Oba to wa lo ye.
Edumare jowo bawa da ilu Oyo si
Amin, Ase
EKO
Eko Akete Ile Ogbon
Eko Aromi sa legbe legbe
Eko aro sese maja
Eko akete ilu okun alagbalugbu omi,
Ta lo ni elomi l’eko? ebiwon pe talo ni abatabutu baba omikomi, talo laabata buutu
baba odo kodo
Eko adele ti angere nsare ju eniyan elese meji lo
Eni to o ba lo si ilu eko tiko ba gbon, Koda, bo lo si ilu oyinbo ko legbon mo
Afefe toni pon wa ni bebe okun ti yin, faaji to ni pan wa ni bebe osa
Eko omo osha nio ose, mase kutere, osha n gbobi, kutere n gbori
Eyin lomo afinju woja marin gbendeke, obun woja n wapa sio sio
Eyo o Aye’le Eyo o, Eyo baba n teyin to n fi golu n sere, eyin oni sanwo onibode, odilee
Ti oju o ba ti ehin igbeti, oju o ni t’eko le. Eko o ni baje o.
ILORIN
Ilorin omo akewu gberu omo kewu sola l’eba Ilorin
Awon omo Ilorin won osebo won osogun amo woni kewu
Ilu totobi togbaye tiko legun, sebi esin legun yin nilu Ilorin
Ilorin ilu to jina sina amo osunmo alijana bi arese pa
Ilorin ilu weri werun, Ilorin omo ola toderin omo akukoja omo afida pa kengba
Eyin lomo atapin oniperin apin, ata tomo olomo fi gbotin won, atoto oto fira okun ida
Omo afonja tiwon ba fibisu lo nla lo nlowo lowo, oloju eni to nje mesuru jamba ara Ilorin kin fi ore sore
Ilu to tobi togbaye tiko legun be niwon lo’rin lode Ilorin tiwon
Omo afonja laya lopo alupirin, bi jagun ogboja jagun ayan lo bi ede bi ede jagun ala kaka jagun arode ija
Ki jagun oto lakaka de, onija agbagbe, onija asunlo, bobawa kesin de jagun abinu gba tori wonlo
Ilorin afonja omo ukuku omo weri werun
Edumare Jowo Bawa Da Ilu Ilorin Si
Ase
OGBOMOSO
Ogbomoso omo ajilete nbi won gbe n jeka ki won oto muko yangan
ogbomoso afogbo ja bi esu odara. Ngba ogbomoso ba se o n ti o se tan
Bo logbon inu osebi ere ni omo ajileten ba olu ware se ni.
Ogun o jaja ki o kogbomoso ri e de inu oko esinmin
Ogbomoso Ajilete si ogo re l’a fe korin, Iwo t’a te s’arin odan, Okan ninu ilu Akin
Ibaruba niwon eledin ese, omo ode bare eti oya
Oun ni baba to se gbogbo won le patapata porogodo
Kekere asa omo ajuuju bala
Agbalagba asa omo ajuuju bala
Kekere ladaba subu tawon ti n je laarin ota
Oloumi kekke lo ti n soko won nile
Kekere lo ti n soko won lóki
Kekere lojo ti n soko won lona iju
ILARO
Omo adiye sun won sebi kuku loku, kiwon to lotatan adiye dide oyan fanda
Ilaro omo erin lonibu omo efon lo nona
Omo pakan lakan leyin jijo awo ni gbori ile omo ina tin jo geregere lori omi
Ilaro omo aran o sunwon e ko nigbale omo oku eko omo ijagudu akara
Ogogo omo e ba oro omo ina esan ogbo jinijinji ama jo’le gerege
Ogogo tin yini lokun lapa omo oku dudu ti koya kunran
Omo kulodo to tideri’lewa omo kinikan o joye lesa, tobawa joye lesa nko ilesanmi lasan loba yin muwon je.
Ogogo lomo agbele jebu, omo yiyo lanyo nile baba tobiyin lomo
Ilaro omo ku la ngberi omo kulodo ao ki wan kuloko tan won di apon
Otojo kotojo tomo kulodo nbo lati oko egan loba pade omi sonte, egbon mu aburo na mu gbogbo eni tomu sonte lomu rogbo dan